Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 31:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nínú Rẹ̀, Olúwa ni mo ti rí ààbò;Má ṣe jẹ́ kí ojú kí ó tì mí;gbà mí nínú òdodo Rẹ.

2. Tẹ́ etí Rẹ sí mi,gbà mí kíákíá;jẹ́ àpáta ààbò mi,jẹ́ odi alágbára láti gbà mí.

3. Ìwọ pàápàá ni àpáta àti ààbò mi,nítorì orúkọ Rẹ máa ṣe ìtọ́ mi tọ́ mi kí o sì ṣe amọ̀nà mi.

4. Yọ mí jáde kúrò nínú àwọ̀n tí wọ́n dẹ pamọ́ fún mi,nítorí ìwọ ni ìsádi mi.

5. Ní ọwọ́ Rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé;ìwọ ni ó tí rà mí padà, Olúwa, Ọlọ́run òtítọ́.

6. Èmi ti kórìíra àwọn ẹni tí ń fi yè sí òrìṣà tí kò níye lórí;ṣùgbọ́n èmi gbẹ́kẹ̀lé Olúwa.

7. Èmi yóò yọ̀, inú mi yóò dùn nínú ìfẹ́ ńlá Rẹ,nítorí ìwọ ti rí ìbìnújẹ́ miìwọ ti mọ̀ ọkàn mi nínú ìpọ́njú.

8. Pẹ̀lú ìwọ kò sì fà mi lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́ìwọ ti fi ẹsẹ̀ mi lé ibi àyè ńlá.

9. Ṣàánú fún mi, ìwọ Olúwa, nítorí mo wà nínú ìpọ́njú;ojú mi fi ìbìnújẹ́ sùn,ọkàn àti ara mi pẹ̀lú.

10. Èmi fi ìbànújẹ́ lo ọjọ́ miàti àwọn ọdún mi pẹ̀lú ìmí ẹ̀dùn;agbára mi ti kùnà nítorí òṣì mi,egungun mi sì ti rún dànù.

Ka pipe ipin Sáàmù 31