Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 23:2-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Ó mú mi dùbúlẹ̀ síbi pápá oko tútùÓ mú mi lọ síbi omí dídákẹ́ rọ́rọ́;

3. Ó mú ọkàn mi padà bọ̀ sípòÓ mú mi lọ sí ọ̀nà ododonítorí orúkọ Rẹ̀.

4. Bí mo tílẹ̀ ń rìnLáàrin àfonífojì òjiji ikú,èmi kì yóò bẹ̀rù ibi kan;nítorí ìwọ wà pẹ̀lú ù mi;ọ̀gọ Rẹ àti ọ̀pá à Rẹwọ́n ń tù mi nínú.

5. Ìwọ tẹ́ tábìlì oúnjẹ sílẹ̀ níwájú ù miní ojú àwọn ọ̀tá à mi;ìwọ ta òróró sí mi ní orí;ago mí sì kún àkún wọ́ sílẹ̀.

6. Nítòótọ, ire àti àánú ni yóò máa tọ̀ mí lẹ́yìnní ọjọ́ ayé è mi gbogbo,èmi yóò sì máa gbé inú ilé Olúwatítí láéláé.

Ka pipe ipin Sáàmù 23