Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 18:28-43 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

28. Ìwọ, Olúwa, jẹ́ kí fìtílà mikí ó máa tàn; Ọlọ́run mi, yí òkùnkùn mi padà sí ìmọ́lẹ̀.

29. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Rẹ̀, èmi ṣare la ogun lọ;pẹ̀lú Ọlọ́run mi mo lè fo odi kan

30. Bí ó ṣe ti Ọlọ́run mi, ọ̀nà Rẹ̀ pé,a ti rídìí ọ̀rọ̀ Olúwaòun ni àpáta ààbòfún gbogbo àwọn tí ó fi ṣe ààbò.

31. Nítorí ta ni ṣe Ọlọ́run bí kò ṣe Olúwa?Ta ní àpátà bí kò ṣe Olúwa wa?

32. Ọlọ́run ni ẹni tí ó fi agbára dì mí ní àmùrèó sì mú ọ̀nà mi pé.

33. Ó ṣe ẹsẹ̀ mi gẹ́gẹ́ bi ẹsẹ̀ àgbọ̀nrín;ó jẹ́ ki n lè dúró lórí ibi gíga.

34. Ó kọ́ ọwọ́ mi ni ogun jíja;apá mi lè tẹ ọrùn idẹ

35. Ìwọ fi àṣà ìṣẹ́gun Rẹ̀ fún mi,ọwọ́ ọ̀tún Rẹ̀ gbé mí sókè;àti ìwà ìpẹ̀lẹ́ Rẹ̀ sọ mi di alágbára àti ẹni ńlá.

36. Ìwọ sọ ìrìn ẹsẹ mi di ńlá ní ìṣàlẹ̀ mi,kí kókó-ẹsẹ̀ mi má ṣe yẹ̀.

37. Èmi lépa àwọn ọ̀tá mi èmi sì bá wọnèmi kò sì padà lẹ́yìn wọn títí a fi run wọ́n.

38. Èmi ṣá wọn ní ọgbẹ́ tí wọn ko fi le è dìde;Wọ́n subú ní abẹ́ ẹsẹ̀ mi.

39. Nítorí ìwọ fi agbára dì mí ní amùrè fún ogun náà;ìwọ ti mú àwọn tí ó dìde si mí tẹríba ní abẹ́ ẹsẹ̀ mi

40. Ìwọ yí ẹ̀yìn àwọn ọ̀ta mí padà sí mièmi sì pa àwọn tí ó kóríra mí run.

41. Wọ́n kígbé fún ìrànlọ́wọ́, ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí yóò rànwọ́n lọ́wọ́.àní sí Olúwa, ṣùgbọ́n kò dá wọn lóhùn

42. Mo lù wọ́n gẹ́gẹ́ bí eruku níwájú afẹ́fẹ́;mo dà wọ́n síta gẹ́gẹ́ bí ẹrọ̀fọ̀.

43. Ìwọ ti gbà mí lọ́wọ́ ìkọlù àwọn ènìyàn;Ìwọ ti fi mí ṣe olórí àwọn orílẹ́ èdè;àwọn ènìyàn ti èmi kò mọ, yóò sì máa sìn mí.

Ka pipe ipin Sáàmù 18