Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 18:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Mo fẹ́ ọ, Olúwa, agbára mi.

2. Olúwa ni àpáta àti odi mi, àti olùgbàlà mi;Ọlọ́run mi ni àpáta mi, ẹni tí mo fi ṣe ibi ìsádi mi.Òun ni àpáta ààbò àti agbára ìgbàlà mi àti ibi ìsádi mi.

3. Mo ké pe Olúwa, ẹni tí ìyìn yẹ fún,a ó sì gbàmí lọ́wọ́ àwọn ọ̀ta à mi.

4. Ìrora ikú yí mi kà,àti ìsàn omi àwọn ènìyàn búbúrú dẹ́rùbà mí.

5. Okùn isà òkú yí mi ká,ìkẹ́kùn ikú dojúkọ mí.

Ka pipe ipin Sáàmù 18