Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 17:5-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Ìrìn mí ti jẹ mọ́ ọ̀nà Rẹ;ẹṣẹ̀ mi kì yóò yọ̀.

6. Èmi ké pè ọ́, Olúwa, nítorí tí iwọ yóò dá mi lóhùndẹ etí Rẹ sími kí o sì gbọ́ àdúrà mi.

7. Fi ìyanu ìfẹ́ ńlá Rẹ hànìwọ tí ó ń pamọ́ ní ọwọ́ ọ̀tún Rẹàwọn tí ó wá ìsádi nínú Rẹ kúrò ní ọwọ́ ọ̀ta wọn.

8. Pa mí mọ́ bí ẹyin ojú Rẹ;fi mí pamọ́ sí abẹ́ òjìji apá Rẹ.

9. Kúrò ní ọwọ́ ọ̀tá tí ó kọjú ìjà sí mi,kúrò ní ọwọ́ àwọn ọ̀ta apani tí ó yí mi ká.

10. Wọ́n pa ọkàn aláìláàánú wọn mọ́,wọ́n sì fi ẹnu wọn sọ̀rọ̀ ìgbéraga.

11. Wọ́n sì mú mi mọ́lẹ̀, wọ́n sì yí mi ká,pẹ̀lú ojú ìṣọ́ra láti sọ́ mi sílẹ̀.

12. Wọn dà bí i kìnnìún tí ebi ń pa fún ìjẹ,àní bí Kìnnìún ńlá tí ó ń ba níbi ìkọ̀kọ̀.

13. Dìde, Olúwa, dojúkọ wọ́n, Rẹ̀ wọ́n sílẹ̀;gbà mí sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹni búburú nípa idà Rẹ.

14. Olúwa, nípa ọwọ́ Rẹ gbà mí kúrò lọ́wọ́ irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀,kúrò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn ayé yìí, tí èrè wọn wà nínú ayé yìí;Ìwọ ń pa ebi àwọn tí ìwọ fẹ́ràn lẹ́nu mọ́;àwọn ọmọ wọn sì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀,wọ́n sì kó ọrọ̀ jọ fún àwọn ọmọ wọn.

15. Ṣùgbọ́n ní tèmi, èmi yóò máa wo ojú Rẹ ní òdodo;nígbà tí èmi bá jí, èmi yóò ní ìtẹ́lọ́rùn nígbà tí èmi bá rí àwòrán Rẹ.

Ka pipe ipin Sáàmù 17