Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 17:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Gbọ́, Olúwa, ẹ̀bẹ̀ òtítọ́ mi;fi etí sí igbe mi.Tẹ́ti sí àdúrà mití kò ti ètè ẹ̀tàn jáde.

2. Kí ìdáláre mi wá láti ọ̀dọ̀ Rẹ;kí ojú Rẹ kí ó rí ohun tí ó tọ́.

3. Ìwọ ti dán àyà mi wò, ìwọ sì yẹ̀ mí wò ní òru.Bí ìwọ bá dán mi wò, ìwọ kì yóò rí ohunkóhunèmi ti pinnu pé ẹnu mi kì yóò ṣẹ̀.

4. Bí ó ṣe ti iṣẹ́ ènìyànnípa ọ̀rọ̀ ẹnu Rẹèmi ti pa ara mi mọ́kúrò ní ọ̀nà àwọn ìkà.

5. Ìrìn mí ti jẹ mọ́ ọ̀nà Rẹ;ẹṣẹ̀ mi kì yóò yọ̀.

6. Èmi ké pè ọ́, Olúwa, nítorí tí iwọ yóò dá mi lóhùndẹ etí Rẹ sími kí o sì gbọ́ àdúrà mi.

7. Fi ìyanu ìfẹ́ ńlá Rẹ hànìwọ tí ó ń pamọ́ ní ọwọ́ ọ̀tún Rẹàwọn tí ó wá ìsádi nínú Rẹ kúrò ní ọwọ́ ọ̀ta wọn.

8. Pa mí mọ́ bí ẹyin ojú Rẹ;fi mí pamọ́ sí abẹ́ òjìji apá Rẹ.

9. Kúrò ní ọwọ́ ọ̀tá tí ó kọjú ìjà sí mi,kúrò ní ọwọ́ àwọn ọ̀ta apani tí ó yí mi ká.

10. Wọ́n pa ọkàn aláìláàánú wọn mọ́,wọ́n sì fi ẹnu wọn sọ̀rọ̀ ìgbéraga.

11. Wọ́n sì mú mi mọ́lẹ̀, wọ́n sì yí mi ká,pẹ̀lú ojú ìṣọ́ra láti sọ́ mi sílẹ̀.

12. Wọn dà bí i kìnnìún tí ebi ń pa fún ìjẹ,àní bí Kìnnìún ńlá tí ó ń ba níbi ìkọ̀kọ̀.

Ka pipe ipin Sáàmù 17