Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 148:3-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Ẹ fi ìyìn fún un,oòrùn àti òṣùpáẸ fi ìyìn fún un,gbogbo ẹ̀yin ìràwọ̀ ìmọ́lẹ̀.

4. Ẹ fi ìyìn fún un,ẹ̀yin ọ̀run àwọn ọ̀run gígaàti ẹ̀yin omi tí ń bẹ ní òkè ọ̀run

5. Ẹ jẹ́ kí wọn kí ó yin orúkọ Olúwanítorí ó pàṣẹ a sì dá wọn

6. Ó fi ìdí wọn múlẹ̀ láé àti láéláéó sì ti ṣe ìlànà kan tí kì yóò já.

7. Ẹ yin Olúwa láti ilẹ̀ ayé wáẹ̀yin ẹ̀dá inú òkun títóbiàti ẹ̀yin ibú òkun

8. Mọ̀nàmọ́ná àti òjò yìnyínìdí omi àti àwọn ìkùùku,ìjì líle tí ń mú ọ̀rọ̀ Rẹ̀ ṣẹ;

9. Òkè ńlá àti gbogbo òkè kékèké,igi eléso àti gbogbo igi kédárì,

10. Àwọn ẹranko ńlá àti ẹran ọ̀sìngbogbo ohun afàyàfà àti àwọn ẹyẹ abìyẹ́:

11. Àwọn ọba ayé àti ènìyàn áye gbogboàwọn ọmọ aládé àti gbogbo àwọn onídájọ́ ayé,

12. Ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrinàwọn arúgbó àti àwọn ọmọdé.

13. Ẹ jẹ́ kí wọn kí ó yin orúkọ Olúwanítorí orúkọ Rẹ̀ nìkan ni ó ní ọláògo Rẹ̀ kọjá ayé àti ọ̀run

14. Ó sì gbé ìwo kan sókè fún àwọn ènìyàn Rẹ̀,ìyìn fún gbogbo ènìyàn mímọ́ Rẹ̀ àní fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,àwọn ènìyàn tí ó súnmọ́ ọ̀dọ̀ Rẹ̀.Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Ka pipe ipin Sáàmù 148