Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 143:4-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Nítorí náà ẹ̀mí mi ṣàárẹ̀ nínú mi;ọkàn mi tí ó wà nínú mi dààmú.

5. Èmi rántí ọjọ́ tí ó ti pẹ́;èmi ń ṣe àṣàrò lórí gbogbo iṣẹ́ Rẹmo sì ṣe àkíyèsí ohun tí ọwọ́ Rẹ ti ṣe.

6. Èmi na ọwọ́ mi jáde sí ọ:òrùgbẹ Rẹ gbẹ ọkàn mi bí i ìyàngbẹ ilẹ̀. Sela

7. Dámilóhùn kánkán, Olúwa; ó Rẹ̀ ẹ̀mí miMá ṣe pa ojú Rẹ mọ́ kúrò lára mitàbí èmi yóò dàbí àwọn tí ó lọ sínú ihò

8. Jẹ́ kí òwúrọ̀ mú ọ̀rọ̀ ìfẹ́ tí kì í kùnà wá fún mi,nítorí èmi ti gbẹ́kẹ̀ mi lé ọ.Fí ọ̀nà tí èmi i bá rìn hàn mí,nítorí sí ọ ni èmi gbé ọkàn mi sókè.

9. Gbà mí kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi, Olúwa,nítorí èmi fí ara mi pamọ́ sínú Rẹ̀.

10. Kọ́ mi láti ṣe ìfẹ́ Rẹ,nítorí ìwọ ni Ọlọ́run mijẹ́ kí ẹ̀mí Rẹ dídáradarí mi sí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú.

Ka pipe ipin Sáàmù 143