Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 143:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Olúwa gbọ̀ àdúrà mi,fetísí igbe mi fún àánú;nínú òtítọ́ àti òdodo Rẹ wá fún ìrànlọ́wọ́ mi

2. Má ṣe mú ìránṣẹ́ Rẹ wá sí ìdájọ́,nítorí kò sí ẹnìkan tí ó wà láàyètí ó ṣe òdodo níwájú Rẹ.

3. Ọ̀ta ń lé pa mi,ó fún mi pa mọ́ ilẹ̀;ó mú mi gbé nínú òkùnkùnbí àwọn tí ó ti kú ti pẹ́.

4. Nítorí náà ẹ̀mí mi ṣàárẹ̀ nínú mi;ọkàn mi tí ó wà nínú mi dààmú.

5. Èmi rántí ọjọ́ tí ó ti pẹ́;èmi ń ṣe àṣàrò lórí gbogbo iṣẹ́ Rẹmo sì ṣe àkíyèsí ohun tí ọwọ́ Rẹ ti ṣe.

6. Èmi na ọwọ́ mi jáde sí ọ:òrùgbẹ Rẹ gbẹ ọkàn mi bí i ìyàngbẹ ilẹ̀. Sela

7. Dámilóhùn kánkán, Olúwa; ó Rẹ̀ ẹ̀mí miMá ṣe pa ojú Rẹ mọ́ kúrò lára mitàbí èmi yóò dàbí àwọn tí ó lọ sínú ihò

Ka pipe ipin Sáàmù 143