Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 14:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Asiwèrè wí nínú ọkàn Rẹ̀ pé,“kò sí Ọlọ́run.”Wọ́n díbàjẹ́, iṣẹ́ wọn sì burú;kò sí ẹnìkan tí ó ṣe rere.

2. Olúwa sì bojú wolẹ̀ láti ọ̀run wálórí àwọn ọmọ ènìyànbóyá ó le rí ẹni tí òye yé,ẹnikẹ́ni tó ń wá Ọlọ́run.

3. Gbogbo wọn sì ti yípadà,gbogbo wọn sì ti díbàjẹ́;kò sì sí ẹni tí ó ń ṣe rere,kò sí ẹnìkan.

4. Ǹjẹ́ olùṣe búburú kò ha ní kọ́ ẹ̀kọ́:àwọn tí ó ń pa ènìyàn mí jẹ bí ẹníjẹ àkàràtí wọn kò sì ké pe Olúwa?

5. Wọ́n wà níbẹ̀, tí a bò mọ́lẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀rù,nítorí Olúwa wà ní àwùjọ àwọn olódodo.

6. Ẹ̀yin olùṣe búburú ba èrò àwọn aláìní jẹ́,ṣùgbọ́n Olúwa ni ààbò wọn.

7. Ìgbàlà àwọn Ísírẹ́lì yóò ti Síónì wá!Nígbà tí Olúwa bá mú ìkólọ àwọn ènìyàn Rẹ̀ padà,jẹ́ kí Jákọ́bù kí ó yọ̀, kí inú Ísírẹ́lì kí ó dùn!

Ka pipe ipin Sáàmù 14