Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 14:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Asiwèrè wí nínú ọkàn Rẹ̀ pé,“kò sí Ọlọ́run.”Wọ́n díbàjẹ́, iṣẹ́ wọn sì burú;kò sí ẹnìkan tí ó ṣe rere.

2. Olúwa sì bojú wolẹ̀ láti ọ̀run wálórí àwọn ọmọ ènìyànbóyá ó le rí ẹni tí òye yé,ẹnikẹ́ni tó ń wá Ọlọ́run.

3. Gbogbo wọn sì ti yípadà,gbogbo wọn sì ti díbàjẹ́;kò sì sí ẹni tí ó ń ṣe rere,kò sí ẹnìkan.

4. Ǹjẹ́ olùṣe búburú kò ha ní kọ́ ẹ̀kọ́:àwọn tí ó ń pa ènìyàn mí jẹ bí ẹníjẹ àkàràtí wọn kò sì ké pe Olúwa?

5. Wọ́n wà níbẹ̀, tí a bò mọ́lẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀rù,nítorí Olúwa wà ní àwùjọ àwọn olódodo.

6. Ẹ̀yin olùṣe búburú ba èrò àwọn aláìní jẹ́,ṣùgbọ́n Olúwa ni ààbò wọn.

Ka pipe ipin Sáàmù 14