Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 136:11-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Ó sì mú Ísírẹ́lì jáde kúrò láàrin wọn;nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

12. Pẹ̀lú ọwọ́ agbára àti apá nínà;nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

13. Fún ẹni tí ó pín òkun pupa ní ìyà;nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

14. Ó sì mú Ísírẹ́lì kọjá láàrin Rẹ̀nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

15. Ṣùgbọ́n ó bi Fáráò àti ogun Rẹ̀ ṣubú nínú òkun pupa;nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

16. Fún ẹni tí ó sin àwọn ènìyàn Rẹ̀ la ihà jánítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

17. Fún ẹni tí ó kọ lu àwọn ọba ńlá;nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

18. Ó sì pa àwọn ọba olókìkínítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

Ka pipe ipin Sáàmù 136