Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 136:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí tí ó ṣeun;nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

2. Ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run àwọn ọlọ́run:nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

3. Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa àwọn Olúwa,nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

4. Fún Òun nìkan tí ń ṣiṣẹ́ ìyanu ńlá;nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

5. Fún ẹni tí ó fi ọgbọ́n dá ọ̀run;nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

Ka pipe ipin Sáàmù 136