Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 122:2-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Ẹsẹ̀ wa yóò dúró ní ẹnu ibodè Rẹ,ìwọ Jérúsálẹ́mù.

3. Jérúsálẹ́mù, ìwọ tí a kọ́ bí ìlútí o fi ara mọ́ra pọ̀ ṣọ̀kan

4. Níbi tí àwọn ẹ̀yà máa ń gòkè lọ,àwọn ẹ̀yà Olúwa,ẹ̀rí fún Ísírẹ́lì, látimáa dúpẹ́ fún orúkọ Olúwa.

5. Nítorí ibẹ̀ ni a gbé ìtẹ́ ìdájọ́ kalẹ̀,àwọn ìtẹ́ ilé Dáfídì.

6. Gbàdúrà fún àlàáfíà Jérúsálẹ́mù;àwọn tí o fẹ́ ọ yóò ṣe rere.

7. Kí àlàáfíà kí ó wà nínú odi Rẹ̀,àti ire nínú ààfin Rẹ̀.

8. Nítorí àwọn ọkùnrin àti àwọn ẹgbẹ́ mièmi yóò wí nísinsìyí pé,kí àlàáfíà kí ó wà nínú Rẹ̀;

Ka pipe ipin Sáàmù 122