Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 115:3-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wa wà lọ́run:tí ó ń ṣe èyí tí ó wù ú.

4. Òrìṣà fàdákà àti wúrà,iṣẹ́ ọwọ́ ènìyàn

5. Wọn ní ẹnu, ṣùgbọ́n wọn kò lè sọ̀rọ̀,wọn ní ojú, ṣùgbọ́n wọn kò fi ríran.

6. Wọ́n ní etí, ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́ràn:wọ́n ní imú, ṣùgbọ́n wọ́n kò fi gbóòórùn

7. Wọ́n ní ọwọ́, ṣùgbọ́n wọn kò lò ó,wọ́n ní ẹṣẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kò rìn;bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kò sọ̀rọ̀ nínú òfin wọn.

8. Àwọn tí ń ṣe wọ́n dàbí wọn;gẹ́gẹ́ bẹ ni olúkúlùkù ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀ Rẹ̀ lé wọn.

9. Ìwọ Ísírẹ́lì gbẹ́kẹ̀lé Olúwa:òun ni ìrànwọ́ àti ààbò wọn

10. Ẹ yin ilé Árónì, gbẹ́kẹ̀lé Olúwa:oun ní ìrànwọ́ àti ààbò wọn

Ka pipe ipin Sáàmù 115