Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 111:4-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Ó ti ṣe iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀, láti máa rántí: Olúwa ni olóore ọ̀fẹ́ àti pé ó kún fún àánú.

5. O ti fi oúnjẹ fún àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ̀:oun ń rántí májẹ̀mú Rẹ̀.

6. Ó ti fi hàn àwọn ènìyàn Rẹ̀ agbára isẹ́ Rẹ̀láti fún wọn ní ilẹ̀lérí ni ìní

7. Iṣẹ́ ọwọ Rẹ̀ jẹ́ òtítọ́ àti ìdájọ́;gbogbo òfin Rẹ̀ sì dájú.

8. Wọ́n dúró láé àti láé,ní òtítọ́ àti òdodo ní a ṣe wọ́n.

9. Ó rán ìràpadà sí àwọn ènìyàn Rẹ̀:ó pàṣẹ májẹ̀mú Rẹ̀ títí láé:mímọ́ àti ọ̀wọ̀ ní orúkọ Rẹ̀.

10. Ìbẹ̀rù Ọlọ́run ni ìpilẹ̀ṣẹ̀ ọgbọ́n:òye dáradára ni yóò máa ṣe òfin Rẹ̀:ìyìn Rẹ̀ dúró láé.

Ka pipe ipin Sáàmù 111