Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 110:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Olúwa sọ fún Olúwa mi, pé ìwọ jòkòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi, títí èmi yóò fi sọ àwọn ọ̀tá Rẹ̀ di àpótí ìtisẹ̀ Rẹ

2. Olúwa yóò na ọ̀pá agbára Rẹ̀láti Síónì wá, ìwọ jọba láàrin àwọn ọ̀tá Rẹ.

3. Àwọn ènìyàn Rẹ jẹ́ ọ̀rẹ́ àtinúwání ọjọ́ ìjáde ogun Rẹ, nínú ẹwà mímọ́,láti inú òwúrọ̀ wá ìwọ ni ìrì ẹwà Rẹ.

4. Olúwa ti búra, kò sí ní yí ọkàn padà pé,ìwọ ní àlúfà títí láé, titẹ̀ àpẹẹrẹ Melekisédékì.

5. Olúwa ní ọwọ́ ọ̀tún Rẹ̀ niyóò lu àwọn ọba bolẹ̀ ni ọjọ́ ìbínú Rẹ̀

6. Yóò ṣe ìdájọ́ láàrin kènfèrí,yóò kún ibùgbé wọn pẹ̀lú òkú ara;yóò fọ́n àwọn olórí ká sí orí ilẹ̀ ayé tí ó gbòòrò.

7. Yóò mú nínú òdò ṣíṣàn ní ọ̀nà:nítorí náà ni yóò ṣe gbe orí sókè.

Ka pipe ipin Sáàmù 110