Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 109:22-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Nítorí pé talákà àti aláìní ni mí,àyà mi sì gbọgbẹ́ nínú mi.

23. Èmi ń kọja lọ bí òjiji tí óńfà sẹ́yìn,mo ń gbọ̀n sókè bí eṣú.

24. Eékún mi di aláìlera nítorí ààwẹ̀ gbígbàẹran ara mi sì gbẹ nítorí àìlera mi.

25. Mo dàbí ẹ̀gàn fún àwọn olùfisùn mi;nígbà tí wọn wò mí, wọn gbọn orí wọn.

26. Ràn mí lọ́wọ́, Olúwa Ọlọ́run mi;gbà mí gẹ́gẹ́ bí ìṣeun ìfẹ́ Rẹ.

27. Jẹ́ kí wọn mọ̀ pé ọwọ́ Rẹ ni èyíwí pé ìwọ, Olúwa, ni o ṣe é.

Ka pipe ipin Sáàmù 109