Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 109:18-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Bí ó ti fi ègún wọ ará Rẹ̀ lásọ bí ẹ̀wùbẹ́ẹ̀ ni kí ó wá si inú Rẹ̀ bí omi

19. Jẹ́ kí o rí fún un bí aṣọ tí a dàbòó níara, àti fún àmùrè ti ó fi gbàjá nígbà gbogbo

20. Èyí ni èrè àwọn ọ̀ta mi làti ọwọ́ Olúwa wá;àti ti àwọn tí ń sọ̀rọ̀ ibi sí ọ̀kàn mi.

21. Ṣùgbọ́n ìwọ, ìwọ ṣe fún mi Olúwa,ṣe rere fún mi nítorí orúkọ RẹNítorí ti àánú Rẹ dara, ìwọ gbà mí

22. Nítorí pé talákà àti aláìní ni mí,àyà mi sì gbọgbẹ́ nínú mi.

23. Èmi ń kọja lọ bí òjiji tí óńfà sẹ́yìn,mo ń gbọ̀n sókè bí eṣú.

24. Eékún mi di aláìlera nítorí ààwẹ̀ gbígbàẹran ara mi sì gbẹ nítorí àìlera mi.

25. Mo dàbí ẹ̀gàn fún àwọn olùfisùn mi;nígbà tí wọn wò mí, wọn gbọn orí wọn.

26. Ràn mí lọ́wọ́, Olúwa Ọlọ́run mi;gbà mí gẹ́gẹ́ bí ìṣeun ìfẹ́ Rẹ.

Ka pipe ipin Sáàmù 109