11. Jẹ́ kí alọ́nilọ́wọ́gbà kí ó mú ohun gbogbo tí ó níjẹ́ kí àléjò kí o kó èrè isẹ́ Rẹ̀ lọ
12. Má ṣe jẹ́ kí ẹnikan ṣe àánú fún untàbí kí wọn káàánú lóríàwọn ọmọ Rẹ̀ aláìní baba
13. Kí a gé àrọ́mọdọ́mọ Rẹ̀ kúròkí orúkọ wọn kí ó parẹ́ ní ìran tí ń bọ̀
14. Kí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba Rẹ̀ kíó wà ní ìrántí ní ọ̀dọ̀ OlúwaMá ṣe jẹ́ kí a yọ ẹ̀ṣẹ̀ ìyá wọn kúrò
15. Jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ wọn kí ó wà ní ìrántí níwájú Olúwakí o le ge ìrántí wọn kúrò lórí ilẹ̀.
16. Nítorí kò rántí láti ṣàánú,ṣùgbọ́n ó ṣe inúnibíní sí ọkùnrin tálákà àti olùpọ́njú,kí ó lè pa oníròbìnújẹ́ ọkàn.
17. Ó fẹ́ràn láti máa mú ègún wá sí orí Rẹ̀:bi inú Rẹ̀ kò ti dùn si ire, bẹ́ẹ̀ ni ki ó jìnnà sí ì.