Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 109:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọlọ́run, ti èmi ń fi ìyìn fúnMá ṣe dákẹ́

2. Nítorí àwọn ènìyàn búburú àti ẹlẹ́tànti ya ẹnu wọn sí miwọ́n ti fi ahọ́n èké sọ̀rọ̀ sí mi

3. Wọn fi ọ̀rọ̀ ìrira yí mi káàkiri;wọ́n bá mi ja láìnídìí

4. Nípo ifẹ̀ mi, wọn ń ṣe ọ̀tá mi,ṣùgbọ́n èmi ń gba àdúrà.

5. Wọ́n sì fi ibi san ire fún miàti ìríra fún ìfẹ́ mi.

6. Yan àwọn ènìyàn búburú láti dojú kọ ọ́jẹ́ kí àwọn olufisùndúró ní ọwọ́ ọ̀tún Rẹ̀.

7. Kí a dá a lẹbi nígbà tí a bá ṣe ìdájọ́kí àdúrà Rẹ̀ kí ó lè di ìkọ̀sílẹ̀

8. Kí ọjọ́ Rẹ̀ kí ó kúrúkí ẹlòmíràn kí ó rọ́pò iṣẹ́ Rẹ̀

9. Kí àwọn ọmọ Rẹ̀ di aláìní babakí aya Rẹ̀ sì di opó

10. Jẹ́ kí àwọn ọmọ Rẹ̀ máa ṣagbe kirikí wọn máa tọrọ ounjẹ jìnnà sí ibi ahoro wọn

11. Jẹ́ kí alọ́nilọ́wọ́gbà kí ó mú ohun gbogbo tí ó níjẹ́ kí àléjò kí o kó èrè isẹ́ Rẹ̀ lọ

12. Má ṣe jẹ́ kí ẹnikan ṣe àánú fún untàbí kí wọn káàánú lóríàwọn ọmọ Rẹ̀ aláìní baba

Ka pipe ipin Sáàmù 109