Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 101:2-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Èmi yóò máa rin ìrìn mi pẹ̀lú ọgbọ́n láìlẹ́sẹ̀, ìgbà wo ni ìwọ yóò wá sí ọ̀dọ̀ mi?Èmi yóò máa rìn ní ilé mi pẹ̀lú àyà pípé.

3. Èmi kì yóò gbé ohun búburú sí iwájú mi:iṣẹ́ àwọn tí o yapa ni èmi kórìírawọn kì yóò rọ̀ mọ́ mi.

4. Agídí ọkàn yóò kúrò lọ́dọ̀ miÈmi kì yóò mọ ènìyàn búburú.

5. Ẹnikẹni tí ó bá ń sọ̀rọ̀ ẹnikejì Rẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀,oun ní èmi yóò gé kúròẹni tí ó bá gbé ojú Rẹ̀ ga tí ó sì ní ìgbéraga àyà,òun ní èmi kì yóò faradà fún.

6. Ojú mi yóò wà lára àwọn olóòtọ́ lórí ilẹ̀,kí wọn kí ó le máa bá mi gbé;ẹni tí o bá ń rìn ọ̀nà pípéòun ni yóò máa sìn mí.

7. Ẹni tí o bá ń ṣe ẹ̀tàn, kì yóò gbé ilé mi,kò sí ẹni tí ń ṣèké ti yóò dúró ní iwájú mi.

8. Ní ojojúmọ́ ní èmi yóò wá máa pa lẹ́nu mọgbogbo àwọn ènìyàn búburú ilẹ̀ náà;èmi yóò gé àwọn olùṣe búburúkúrò ní ìlú Olúwa.

Ka pipe ipin Sáàmù 101