Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Rúùtù 4:9-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Nígbà náà ni Bóásì wí fún àwọn àgbààgbà àti àwọn mìíràn tí ó wà ní ibẹ̀ pé, “Gbogbo yín jẹ́ ẹlẹ́rìí mi ní òní wí pé mo ti ra ohun gbogbo tí í ṣe ti Elimélékì àti àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin méjèèjì: Málíónì àti Kílíónì lọ́wọ́ Náómì.

10. Ní àfikún, mo ra Rúùtù ará Móábù opó Málíónì padà láti di aya mi. Èyí tí yóò mú kí orúkọ ọkùnrin òkú náà wà pẹ̀lú ohun-ìní rẹ̀, kí ìran rẹ̀ má ba à lè parẹ́ láàrin àwọn ẹbí rẹ̀ àti ìlú rẹ̀. Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí ní òní.”

11. Nígbà náà ni àwọn àgbààgbà àti àwọn ènìyàn tí ó wà ní ibẹ̀ dáhùn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, àwa ni ẹlẹ́rìí, kí Olúwa jẹ́ kí obìnrin tí ó ń bọ̀ wá sí inú ilẹ̀ rẹ dàbí Rákélì àti Léà láti ara àwọn ẹni tí gbogbo ìdílé Ísírẹ́lì ti jáde wá. Kí ìwọ sì di ọlọ́rọ̀ ní ìran Éfúráta àti olókìkí ní ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.

12. Kí Olúwa fún ọ ní ọmọ tí yóò mú ìdílé rẹ dàbí ti Pérésì, ọmọkùnrin tí Támárì bí fún Júdà láti ipaṣẹ̀ ọ̀dọ́mọbìnrin yìí.”

13. Báyìí ni Bóásì ṣe mú Rúùtù, tí ó sì di aya rẹ̀. Nígbà náà ni ó wọlé tọ aya rẹ̀, Olúwa sì mú kí ó lóyùn, ó sì bí ọmọ ọkùnrin kan.

14. Àwọn obìnrin sì wí fún Náómì pé, “Ìyìn ni fún Olúwa tí kò fi ọ sílẹ̀ ní òní yìí láìní ìbátan, Olùràpadà. Kí ọmọ náà di olókìkí ní Ísírẹ́lì.

15. Yóò tún ayé rẹ ṣe, yóò sì dáàbò bò ọ́ ní ọjọ́ ogbó rẹ. Nítorí pé ìyàwó ọmọ rẹ, èyí tí ó sàn fún ọ ju ọmọkùnrin méje lọ, tí ó sì fẹ́ràn rẹ ni ó bí ọmọ yìí fún.”

Ka pipe ipin Rúùtù 4