Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Rúùtù 4:6-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Nígbà náà ni ọkùnrin náà dáhùn sí èyí pé, “Nípa ti èyí, èmi kò le rà á padà, nítorí pé, ọmọ rẹ, ọkùnrin yóò wá jẹ́ ajogún àwọn ohun-ìní mi pẹ̀lú. Rà á fún ara rẹ, èmi kò le ṣe é.”

7. Ní ayé ìgbà a nì, kí a tó le sọ wí pé ohun ìràpadà tàbí pàsípàrọ̀ ohun-ìní, fi ìdí múlẹ̀ ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì, ẹnìkan ni láti yọ bàtà rẹ̀ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ̀ kí ó sì fi fún ẹnikejì, ó jẹ́ òfin fún ẹni tí ó fẹ́ rà á. Nípa ṣíṣe èyí, àwọn ará Ísírẹ́lì fihàn wí pé ọ̀rọ̀ náà ti fìdímúlẹ̀.

8. Nítorí náà, nígbà tí ọkùnrin náà sọ fún Bóásì wí pé, “Ìwọ rà á fúnràrẹ,” ó yọ bàtà rẹ̀ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ̀.

9. Nígbà náà ni Bóásì wí fún àwọn àgbààgbà àti àwọn mìíràn tí ó wà ní ibẹ̀ pé, “Gbogbo yín jẹ́ ẹlẹ́rìí mi ní òní wí pé mo ti ra ohun gbogbo tí í ṣe ti Elimélékì àti àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin méjèèjì: Málíónì àti Kílíónì lọ́wọ́ Náómì.

10. Ní àfikún, mo ra Rúùtù ará Móábù opó Málíónì padà láti di aya mi. Èyí tí yóò mú kí orúkọ ọkùnrin òkú náà wà pẹ̀lú ohun-ìní rẹ̀, kí ìran rẹ̀ má ba à lè parẹ́ láàrin àwọn ẹbí rẹ̀ àti ìlú rẹ̀. Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí ní òní.”

11. Nígbà náà ni àwọn àgbààgbà àti àwọn ènìyàn tí ó wà ní ibẹ̀ dáhùn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, àwa ni ẹlẹ́rìí, kí Olúwa jẹ́ kí obìnrin tí ó ń bọ̀ wá sí inú ilẹ̀ rẹ dàbí Rákélì àti Léà láti ara àwọn ẹni tí gbogbo ìdílé Ísírẹ́lì ti jáde wá. Kí ìwọ sì di ọlọ́rọ̀ ní ìran Éfúráta àti olókìkí ní ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.

Ka pipe ipin Rúùtù 4