Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Rúùtù 2:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Náómì ní ìbátan kan láti ìdílé Elimélékì ọkọ rẹ̀, aláàánú ọlọ́rọ̀, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Bóásì.

2. Rúùtù, ará Móábù sì wí fún Náómì pé, “Jẹ́ kí èmi kí ó lọ sí inú oko láti ṣa ọkà tí àwọn olùkórè fi sílẹ̀ ní ọ̀dọ̀ ẹnikẹ́ni tí èmi yóò bá ojú rere rẹ̀ pàdé.”Náómì sì sọ fún-un pé, “Má a lọ, ọmọbìnrin mi.”

3. Rúùtù sì jáde lọ láti ṣa ọkà tí àwọn olùkórè fi sílẹ̀ lẹ́yìn wọn. Ó wá jẹ́ wí pé inú oko Bóásì tí ó ti ìdílé Elimélékì wá ni ó lọ láé mọ̀ ọ́ mọ̀.

4. Nígbà náà ni Bóásì dé láti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù tí ó sì kí àwọn olùkórè wí pé, “Kí Olúwa wà pẹ̀lú yín.”Wọ́n sì dá a lóhùn padà pé, “Kí Olúwa bùkún fún ọ.”

5. Bóásì sì béèrè lọ́wọ́ olórí àwọn olùkórè wí pé, “Ti ta ni ọ̀dọ́mọbìnrin yẹn?”

6. Ìránṣẹ́ tí ó jẹ́ olórí àwọn olùkórè náà sì fèsì pé, “Ọ̀dọ́mọbìnrin ará Móábù tí ó tẹ̀lé Náómì wá láti ilẹ̀ Móábù ni.

7. Ó sọ wí pé, ‘Kí ń jọ̀wọ́ jẹ́ kí òun máa ṣa ọkà lẹ́yìn àwọn olùkórè.’ Ó sì ti ń ṣe iṣẹ́ kárakára láti òwúrọ̀ títí di ìsinsìn yìí nínú oko àyàfi ìgbà tí ó lọ láti sinmi fún ìgbà díẹ̀ lábẹ́ ibojì.”

8. Nígbà náà ni Bóásì sọ fún Rúùtù pé, “Gbọ́ ọmọbìnrin mi, má ṣe lọ sí oko mìíràn láti ṣa ọkà, má sì ṣe kúrò ní ibi. Dúró níbí pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́-bìnrin mi.

9. Wo ibi tí wọ́n ti ń kórè kí o sì máa tẹ̀lé àwọn obìnrin. Mo ti pàṣẹ fún àwọn ọkùnrin kí wọ́n má ṣe fi ọwọ́ kàn ọ́. Nígbàkugbà tí òǹgbẹ bá sì ń gbẹ ọ́, lọ kí ó sì mu omi nínú àmù èyí tí àwọn ọkùnrin ti pọn omi sí nínú.”

Ka pipe ipin Rúùtù 2