Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Rúùtù 2:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Náómì ní ìbátan kan láti ìdílé Elimélékì ọkọ rẹ̀, aláàánú ọlọ́rọ̀, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Bóásì.

2. Rúùtù, ará Móábù sì wí fún Náómì pé, “Jẹ́ kí èmi kí ó lọ sí inú oko láti ṣa ọkà tí àwọn olùkórè fi sílẹ̀ ní ọ̀dọ̀ ẹnikẹ́ni tí èmi yóò bá ojú rere rẹ̀ pàdé.”Náómì sì sọ fún-un pé, “Má a lọ, ọmọbìnrin mi.”

3. Rúùtù sì jáde lọ láti ṣa ọkà tí àwọn olùkórè fi sílẹ̀ lẹ́yìn wọn. Ó wá jẹ́ wí pé inú oko Bóásì tí ó ti ìdílé Elimélékì wá ni ó lọ láé mọ̀ ọ́ mọ̀.

4. Nígbà náà ni Bóásì dé láti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù tí ó sì kí àwọn olùkórè wí pé, “Kí Olúwa wà pẹ̀lú yín.”Wọ́n sì dá a lóhùn padà pé, “Kí Olúwa bùkún fún ọ.”

5. Bóásì sì béèrè lọ́wọ́ olórí àwọn olùkórè wí pé, “Ti ta ni ọ̀dọ́mọbìnrin yẹn?”

6. Ìránṣẹ́ tí ó jẹ́ olórí àwọn olùkórè náà sì fèsì pé, “Ọ̀dọ́mọbìnrin ará Móábù tí ó tẹ̀lé Náómì wá láti ilẹ̀ Móábù ni.

Ka pipe ipin Rúùtù 2