Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Rúùtù 1:20-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Náómì sì dáhùn wí pé, “Ẹ má ṣe pè mí ní Náómì. Ẹ pè mí ní Márà (Ìkorò), nítorí wí pé Olódùmarè ti mú kí ayé mi di kíkorò.

21. Mo jáde ní kíkún, ṣùgbọ́n Olúwa mú mi padà ní òfo. Nítorí náà kíń ló dé tí ẹ fi ń pè mí ní Náómì, nígbà tí Olódùmarè ti kọ̀ mí sílẹ̀, tí ó sì mú ìdààmú bá mi?”

22. Báyìí ni Náómì ṣe padà láti Móábù pẹ̀lú Rúùtù, ará Móábù ìyàwó ọmọ rẹ̀. Wọ́n gúnlẹ̀ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ní ìbẹ̀rẹ̀ ìkórè ọkà bálì.

Ka pipe ipin Rúùtù 1