Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Rúùtù 1:13-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. ṣé ẹ̀yin le è dúró dìgbà tí wọ́n bá dàgbà láì fẹ́ ọkọ mìíràn nítorí wọn ni? Rárá, ẹ̀yin ọmọbìnrin mi. Ó jẹ́ ohun ìbànújẹ́ fún mi ju bí ó ti jẹ́ fún ẹ̀yin lọ nítorí pé ọwọ́ Olúwa ti fìyà jẹ mi lọ́nà tó pamí lára gidi.”

14. Lẹ́ẹ̀kan sí i, wọ́n tún sunkún kíkorò. Nígbà náà ní Órípà fi ẹnu ko ìyá ọkọ rẹ̀ ní ẹnu wí pé ó dìgbà, ṣùgbọ́n Rúùtù dì mọ́ ọn síbẹ̀.

15. Náómì wí pé, “Wòó, arábìnrin rẹ ti padà lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀ àti òrìṣà rẹ̀, ìwọ náà padà pẹ̀lú rẹ̀.”

16. Ṣùgbọ́n Rúùtù dáhùn wí pé, “Má ṣe rọ̀ mí láti fi ọ́ sílẹ̀ tàbí láti padà lẹ́yìn rẹ. Ibi tí o bá lọ ní èmi yóò lọ, ibi ti ó bá dúró ni èmi yóò dúró, àwọn ènìyàn rẹ ni yóò jẹ́ ènìyàn mi, Ọlọ́run rẹ ni yóò sì jẹ́ Ọlọ́run, mi,

17. Nibi tí o bá kú sí ni èmi yóò kú sí, níbẹ̀ ni wọn yóò sì sin mí sí. Kí Olúwa jẹ mí ní ìyà tí ó lágbára, bí ohunkóhun bí kò ṣe ikú bá yà wá.”

18. Nígbà tí Náómì rí i wí pé Rúùtù ti pinnu láti tẹ̀lé òun kò rọ̀ láti padà mọ́.

19. Àwọn méjèèjì sì ń lọ títí wọ́n fi dé ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, ariwo ìpadàbọ̀ wọn gba ìlú kan, àwọn obìnrin ibẹ̀ sì kígbe ní ohùn rara wí pé, “Náómì ni èyí bí?”

20. Náómì sì dáhùn wí pé, “Ẹ má ṣe pè mí ní Náómì. Ẹ pè mí ní Márà (Ìkorò), nítorí wí pé Olódùmarè ti mú kí ayé mi di kíkorò.

21. Mo jáde ní kíkún, ṣùgbọ́n Olúwa mú mi padà ní òfo. Nítorí náà kíń ló dé tí ẹ fi ń pè mí ní Náómì, nígbà tí Olódùmarè ti kọ̀ mí sílẹ̀, tí ó sì mú ìdààmú bá mi?”

22. Báyìí ni Náómì ṣe padà láti Móábù pẹ̀lú Rúùtù, ará Móábù ìyàwó ọmọ rẹ̀. Wọ́n gúnlẹ̀ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ní ìbẹ̀rẹ̀ ìkórè ọkà bálì.

Ka pipe ipin Rúùtù 1