Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 8:5-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Ẹ̀yin aláìmọ́kan, ẹ kọ́gbọ́n;ẹ̀yin aláìgbọ́n, ẹ gba òye.

6. Tẹ́tí, nítorí mo ní àwọn ohun iyebíye láti sọ;Mo ya ẹnu mi láti sọ àwọn ohun tí ó tọ̀nà,

7. Ẹnu mi ń sọ ohun tí í ṣe òtítọ́,nítorí ètè mi kórìíra ibi.

8. Gbogbo ọrọ ẹnu mi ni ó tọ́,kò sí èyí tí ó jẹ́ ẹ̀tàn tàbí àyídáyídà níbẹ̀

9. Fún Olóye gbogbo rẹ̀ ni ó tọ̀nà;wọ́n jẹ́ aláìlẹ́gàn fún gbogbo ẹni tí ó ní ìmọ̀.

10. Yan ẹ̀kọ́ mi dípò fàdákà,ìmọ̀ dípò o wúrà àṣàyàn,

11. Nítorí ọgbọ́n ṣe iyebíye jù ìyùn lọ,kò sí ohun tí ọkàn rẹ̀ fẹ́ tí a sì le fi wé e.

12. “Èmi, ọgbọ́n ń gbé pẹ̀lú òye;mo ní ìmọ̀ àti ọgbọ́n-inú.

13. Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìkóòríra ibimo kóríra ìgbéraga àti agídí,ìwà ibi àti ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.

14. Ìmọ̀ràn àti ọgbọ́n tí ó yè kooro jẹ́ tèmimo ní òye àti agbára.

15. Nípaṣẹ̀ mi ni ọba ń ṣàkósotí àwọn aláṣẹ sì ń ṣe òfin tí ó dára

16. Nípasẹ̀ mi àwọn ọmọ aládé ń ṣàkósoàti gbogbo ọlọ́lá tí ń ṣàkóso ilẹ̀ ayé.

17. Mo fẹ́ràn àwọn tí ó fẹ́ràn miàwọn tí ó sì wá mi rí mi.

18. Lọ́dọ̀ mi ni ọrọ̀ àti ọlá wàỌrọ̀ tí í tọ́jọ́ àti ìgbéga rere.

19. Èso mi dára ju wúrà dáradára lọ;ohun tí mò ń mú wá ju àṣàyàn fàdákà lọ.

20. Mò ń rìn ní ọ̀nà òdodo,ní ojú ọ̀nà òtítọ́,

21. mò ń fi ọrọ̀ fún gbogbo àwọn tí ó fẹ́ràn mimo sì ń mú kí ilé ìṣúra wọn kún.

22. “Èmi ni Olúwa kọ́kọ́ dá nínú iṣẹ́ rẹ̀.Ṣáájú àwọn iṣẹ́ rẹ̀ àtijọ́;

23. A ti yàn mí láti ayérayé,láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, kí ayé tó bẹ̀rẹ̀.

Ka pipe ipin Òwe 8