Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 8:29-36 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

29. Nígbà tí ó ṣe ààlà fún omi òkunkí omi má baà kọjá ààlà àṣẹ rẹ̀,àti nígbà tí ó pààlà ìpìlẹ̀ ayé.

30. Nígbà náà èmi ni gbẹ́nàgbẹ́nà ẹ̀gbẹ́ẹ rẹ̀mo kún fún inú dídùn lójoojúmọ́,mo ń yọ̀ nígbà gbobgbo níwájú rẹ̀

31. mo ń yọ̀ nínú gbogbo àgbáyé tí ó dámo sì ní inú dídùn sí àwọn ọmọ ènìyàn.

32. “Nítorí náà báyìí, ẹ̀yin ọmọ mi,ìbùkún ni fún àwọn tí ó pa ọ̀nà mi mọ́

33. fetí sí ìtọ́ṣọ́nà mi kí o sì gbọ́n;má ṣe pa á tì sápá kan.

34. Ìbùkún ni fún ẹni tí ó fetí sílẹ̀ sí mi,tí ń sọ́nà ní ẹnu ọ̀nà mi lójoojúmọ́,tí ń dúró ní ẹnu ọ̀nà mi.

35. Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá rí mi rí ìyèó sì rí ojú rere gbà lọ́dọ̀ Olúwa.

36. Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ̀ láti rí ń pa ara rẹ̀ láragbogbo ẹni tí ó kórira mi fẹ́ ikú.”

Ka pipe ipin Òwe 8