Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 8:16-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Nípasẹ̀ mi àwọn ọmọ aládé ń ṣàkósoàti gbogbo ọlọ́lá tí ń ṣàkóso ilẹ̀ ayé.

17. Mo fẹ́ràn àwọn tí ó fẹ́ràn miàwọn tí ó sì wá mi rí mi.

18. Lọ́dọ̀ mi ni ọrọ̀ àti ọlá wàỌrọ̀ tí í tọ́jọ́ àti ìgbéga rere.

19. Èso mi dára ju wúrà dáradára lọ;ohun tí mò ń mú wá ju àṣàyàn fàdákà lọ.

20. Mò ń rìn ní ọ̀nà òdodo,ní ojú ọ̀nà òtítọ́,

21. mò ń fi ọrọ̀ fún gbogbo àwọn tí ó fẹ́ràn mimo sì ń mú kí ilé ìṣúra wọn kún.

22. “Èmi ni Olúwa kọ́kọ́ dá nínú iṣẹ́ rẹ̀.Ṣáájú àwọn iṣẹ́ rẹ̀ àtijọ́;

23. A ti yàn mí láti ayérayé,láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, kí ayé tó bẹ̀rẹ̀.

24. Nígbà tí kò tíì sí òkun, ni a ti bí minígbà tí kò tíì sí ìsun tí ó ní omi nínú;

25. kí a tó fi àwọn òkè sí ipò wọn,ṣáájú àwọn òkè ni a ti bí mi,

26. kí ó tó dá ilẹ̀ ayé tàbí àwọn oko rẹ̀tàbí èyíkéyìí nínú eruku ayé.

27. Mo wà níbẹ̀ nígbà tí ó fi àwọn ọ̀run sí ipò wọn,nígbà tí ó fi òṣùwọ̀n àyíká sórí ibú omi,

28. Nígbà tí ó ṣẹ̀dá òfuurufú lókètí ó sì fi oríṣun ibú omi sí ipò rẹ̀ láì le è yẹṣẹ̀,

29. Nígbà tí ó ṣe ààlà fún omi òkunkí omi má baà kọjá ààlà àṣẹ rẹ̀,àti nígbà tí ó pààlà ìpìlẹ̀ ayé.

30. Nígbà náà èmi ni gbẹ́nàgbẹ́nà ẹ̀gbẹ́ẹ rẹ̀mo kún fún inú dídùn lójoojúmọ́,mo ń yọ̀ nígbà gbobgbo níwájú rẹ̀

Ka pipe ipin Òwe 8