Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 7:13-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Ó dìí mú, ó sì fẹnu kò ó ní ẹnupẹ̀lú ojú dídín ó wí pé:

14. “Mo ní ọrẹ àlàáfíà ní ilé;lónìí ni mo san ẹ̀jẹ́ mi.

15. Nítorí náà ni mo ṣe jáde wá pádé è rẹ;mo wá ọ káàkiri mo sì ti rí ọ!

16. Mo ti tẹ́ ibùṣùn mipẹ̀lú aṣọ aláràbarà láti ilẹ̀ Éjíbítì.

17. Mo ti fi nǹkan Olóòórùn dídùn sí ibùṣùn mibí i míra, álóè àti kínámónì.

18. Wá, jẹ́ kí a lo ìfẹ́ papọ̀ ní kíkún títí di àárọ̀;jẹ́ kí a gbádùn ara wa pẹ̀lú ìfẹ́!

19. Ọkọ ọ̀ mi ò sí nílé;ó ti lọ sí ìrìnàjò jínjìn.

20. Ó mú owó púpọ̀ lọ́wọ́kò sì ní darí dé kí ó tó di ọ̀sán.”

21. Pẹ̀lú ọ̀rọ̀ dídùn ó sì í lọ́nà;ó tàn án jẹ pẹ̀lú ẹnu dídùn.

22. Kíákíá ni ó tẹ̀lé ebí i màlúù tí ń lọ sí odò ẹranbí àgbọ̀nrín tí ó fẹ́ kẹsẹ̀ bọ pàkúté

23. títí tí ọ̀kọ̀ fi gún un ní ẹ̀dọ̀,bí ẹyẹ ṣe ń fẹ́ wọ inú okùn,Láì mọ̀ pé yóò gba ẹ̀mí òun.

24. Nítorí náà báyìí ẹ̀yin ọmọ mi, tẹ́tí sí mifọkàn sí nǹkan tí mo sọ.

25. Má ṣe jẹ́ kí ọkàn rẹ kí ó yà sí ọ̀nà rẹ̀,tàbí kí ó rìn lọ sí ipa ọ̀nà rẹ̀.

26. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn tí ó ti fà lulẹ̀Ogunlọ́gọ̀ àwọn alágbára ni ó ti pa.

27. Ilé e rẹ̀ ni ọ̀nà tààra sí iṣà òkú,tí ó lọ tààra sí àgbàlá ikú.

Ka pipe ipin Òwe 7