Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 4:16-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Nítorí wọn kò le sùn àyàfi tí wọ́n bá ṣe ibi,wọn kò ní tòògbé àyàfi tí wọ́n bá gbé ẹlòmíràn ṣubú

17. Wọ́n ń jẹ oúnjẹ ìwà búrurúwọ́n sì ń mu wáìnì ìwà ìkà.

18. Ipa ọ̀nà Olódodo dàbí àṣẹ̀ṣẹ̀yọ oòrùntí ń tànmọ́lẹ̀ sí i títí ọjọ́ fi kanrí

19. ṣùgbọ́n ọ̀nà ènìyàn búburú dàbí òkùnkùn biribiri;wọn kò mọ ohun tí ó ń mú wọn kọsẹ̀.

20. Ọmọ mi, tẹ́tí sí ohun tí mo sọ;fetísílẹ̀ dáradára sí ọ̀rọ̀ mi

21. Má ṣe jẹ́ kí wọ́n rá mọ́ ọ lójúpa wọ́n mọ́ sínú ọkàn rẹ;

22. Nítorí ìyè ni wọ́n jẹ́ fún gbogbo ẹni tí ó rí wọnàti ìlera fún gbogbo ara ènìyàn

23. Ju gbogbo nǹkan tó kù lọ, pa ọkàn rẹ mọ́Nítorí òun ni oríṣun ìyè,

24. mú àrékérekè kúrò ní ẹnu rẹ;sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìṣọkúṣọ jìnnà réré sí ẹnu rẹ.

25. Jẹ́ kí ojú ù rẹ máa wo iwájú,jẹ́ kí ìwo ojú ù rẹ máa wo ọ̀kánkán iwájú rẹ sáá.

Ka pipe ipin Òwe 4