Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 29:23-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. Ìgbéraga ènìyàn a máa sọ ọ́ di ẹni ilẹ̀ṣùgbọ́n onírẹ̀lẹ̀ ènìyàn a máa gba iyì kún iyì.

24. Ẹni tí ó ń ran olè lọ́wọ́ gan an ni ọ̀ta rẹ̀O ń gbọ́ epe olóhun kò sì le è fọhùn.

25. Ìbẹ̀rù ènìyàn kan yóò sì di ìdẹkùnṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bẹ̀rù Olúwa wà láìléwu.

26. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ń wá ojúrere alákòóṣo,ṣùgbọ́n láti ọdọ Olúwa ni ènìyàn tí ń gba ìdájọ́ òdodo.

27. Olódodo kórìíra àwọn aláìsòótọ́:ènìyàn búburú kórìíra olódodo.

Ka pipe ipin Òwe 29