Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 29:17-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Bá ọmọ rẹ wí, yóò sì fún ọ ní àlàáfíàyóò sì mú inú dídùn wá sí inú ọkàn rẹ.

18. Níbi tí kò ti sí ìfihàn, àwọn ènìyàn a gbé ìgbé ayé àìbìkítà.Ṣùgbọ́n ìbùkún ní fún àwọn tí ń pa òfín mọ́.

19. A kò le fi ọ̀rọ̀ lásán kìlọ̀ fún ìránṣẹ́bí ó tilẹ̀ yé e, kò ní kọbi-ara-síi.

20. Njẹ́ ó rí ènìyàn tí ń kánjú sọ̀rọ̀?Ìrètí wà fún aláìgbọ́n jù ú lọ.

21. Bí ènìyàn kan bá kẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ lákẹ̀ẹ́jù láti kékeréyóò mú ìbànújẹ́ wá ní ìgbẹ̀yìn.

22. Oníbìínú ènìyàn a ru ìjà sókè,Onínú-fùfù ènìyàn a sì máa dá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀.

23. Ìgbéraga ènìyàn a máa sọ ọ́ di ẹni ilẹ̀ṣùgbọ́n onírẹ̀lẹ̀ ènìyàn a máa gba iyì kún iyì.

24. Ẹni tí ó ń ran olè lọ́wọ́ gan an ni ọ̀ta rẹ̀O ń gbọ́ epe olóhun kò sì le è fọhùn.

25. Ìbẹ̀rù ènìyàn kan yóò sì di ìdẹkùnṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bẹ̀rù Olúwa wà láìléwu.

26. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ń wá ojúrere alákòóṣo,ṣùgbọ́n láti ọdọ Olúwa ni ènìyàn tí ń gba ìdájọ́ òdodo.

27. Olódodo kórìíra àwọn aláìsòótọ́:ènìyàn búburú kórìíra olódodo.

Ka pipe ipin Òwe 29