Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 28:9-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Bí ẹnikẹ́ni bá kọ etí ikún sí òfin,kódà àdúrà rẹ̀ jẹ́ ìríra.

10. Ẹni tí ó mú olódodo rìn ọ̀nà búburúyóò bọ́ sínú pàkúté ara rẹ̀ṣùgbọ́n aláìlẹ́gàn yóò gba ogún rere.

11. Ọlọ́rọ̀ ènìyàn le è gbọ́n lójú ara rẹ̀ṣùgbọ́n talákà tí ó ní òye rí ìdí, rẹ̀.

12. Nígbà tí olódodo ń lékè ariwo ayọ̀ ta;ṣùgbọ́n nígbà tí ènìyàn búburú gorí òye, àwọn ènìyàn a na pápá bora.

13. Ẹni tí ó bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀ kì í ṣe rere,ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá jẹ́wọ́ tí ó sì kọ̀ wọ́n sílẹ̀ máa ń rí àánú gbà.

14. Ìbùkún ni fún ènìyàn náà tí ó bẹ̀rù Olúwa nígbà gbogboṣùgbọ́n ẹni tí ó ṣé ọkàn rẹ̀ le bọ́ sínú wàhálà.

15. Bí kìnnìún tí ń ké tàbí Béárì tí ń halẹ̀ni ènìyàn búburú tí ń jọba lórí àwọn aláìlágbára.

16. Ọba tí ó jẹ gàba lórí ìlú láì gbàmọ̀ràn kò gbọ́nṣùgbọ́n ẹni tí ó kórìíra èrè ìjẹkújẹ yóò gbádùn ọjọ́ gígùn.

17. Ẹni tí ọkàn rẹ̀ kò balẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ìpànìyànyóò máa joró rẹ̀ títí ikúmá ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ràn án lọ́wọ́.

18. Ẹni tí ìrìn rẹ̀ kò ní àbùkù wà láìléwuṣùgbọ́n ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ayípadà yóò ṣubú lójijì.

19. Ẹni tí ó bá ro ilẹ̀ rẹ̀ yóò ní oúnjẹ lọ́pọ̀lọpọ̀ṣùgbọ́n ẹni tí ń lé ohun aṣán yóò kún fún òsì.

20. Olóòótọ́ ènìyàn yóò rí ìbùkún gbà gan anṣùgbọ́n ẹni tí ojú ń kán láti di ọlọ́rọ̀ kì yóò lọ, láìjìyà.

Ka pipe ipin Òwe 28