Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 28:6-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Ó sàn láti jẹ́ talákà tí ìrìn rẹ̀ jẹ́ aláìlábùkùju ọlọ́rọ̀ tí ọ̀nà rẹ̀ rí pálapàla.

7. Ẹni tí ó pa òfin mọ́ jẹ́ olóye ọmọṣùgbọ́n ẹni tí ó bá jẹgúdújẹrá kẹ́gbẹ́ dójú ti baba rẹ̀.

8. Ẹni tí ó mú ọrọ̀ rẹ̀ di púpọ̀ nípa èrè àjẹjùń kó o jọ fún ẹlòmìíràn, tí yóò ní àánú àwọn talákà.

9. Bí ẹnikẹ́ni bá kọ etí ikún sí òfin,kódà àdúrà rẹ̀ jẹ́ ìríra.

10. Ẹni tí ó mú olódodo rìn ọ̀nà búburúyóò bọ́ sínú pàkúté ara rẹ̀ṣùgbọ́n aláìlẹ́gàn yóò gba ogún rere.

11. Ọlọ́rọ̀ ènìyàn le è gbọ́n lójú ara rẹ̀ṣùgbọ́n talákà tí ó ní òye rí ìdí, rẹ̀.

12. Nígbà tí olódodo ń lékè ariwo ayọ̀ ta;ṣùgbọ́n nígbà tí ènìyàn búburú gorí òye, àwọn ènìyàn a na pápá bora.

13. Ẹni tí ó bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀ kì í ṣe rere,ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá jẹ́wọ́ tí ó sì kọ̀ wọ́n sílẹ̀ máa ń rí àánú gbà.

14. Ìbùkún ni fún ènìyàn náà tí ó bẹ̀rù Olúwa nígbà gbogboṣùgbọ́n ẹni tí ó ṣé ọkàn rẹ̀ le bọ́ sínú wàhálà.

15. Bí kìnnìún tí ń ké tàbí Béárì tí ń halẹ̀ni ènìyàn búburú tí ń jọba lórí àwọn aláìlágbára.

16. Ọba tí ó jẹ gàba lórí ìlú láì gbàmọ̀ràn kò gbọ́nṣùgbọ́n ẹni tí ó kórìíra èrè ìjẹkújẹ yóò gbádùn ọjọ́ gígùn.

Ka pipe ipin Òwe 28