Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 27:2-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Jẹ́ kí ẹlòmíràn yìn ọ́ dípò ẹnu ara rẹàní ẹlòmíràn, kì í ṣe ètè ìwọ fúnra rẹ.

3. Òkúta wúwo, erùpẹ̀ sì wúwoṣùgbọ́n ìmúbínú un aṣiwèrè wúwo ju méjèèjì lọ.

4. Ìbínú ni ìkà, ìrunú sì burú púpọ̀ṣùgbọ́n tani ó le è dúró níwájú owú?

5. Ìbániwí gbangba sànju ìfẹ́ ìkọ̀kọ̀ lọ.

6. Ọgbẹ́ láti ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ ṣe é gbẹ́kẹ̀léṣùgbọ́n ọ̀tá máa ń fẹnu-koni-lẹ́nu púpọ̀.

7. Kódà oyin kò dùn lẹ́nu ẹni tí ó ti yóṣùgbọ́n òróòro gan an dùn lẹ́nu ẹni tí ebi ń pa.

8. Bí ẹyẹ tí ó ṣáko lọ kúrò níbi ìtẹ́ rẹ̀ni ènìyàn tí ó ṣáko lọ kúrò ní ilé rẹ̀.

9. Ìpara olóòórùn dídùn àti tùràrí ń mú ayọ̀ wá sínú ọkànbẹ́ẹ̀ ni inú dídùn láti ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ ń wá láti inú ìmọ̀ràn tí ó Ṣàkóso.

10. Má ṣe kọ ọ̀rẹ́ rẹ àti ọ̀rẹ́ baba rẹ sílẹ̀,má sì ṣe lọ sílé arákùnrin rẹ nígbà tí ìdàámú dé bá ọó sàn kí o jẹ́ aládúúgbò tí ó súnmọ́ ni ju arákùnrin tí ó jìnnà síni.

11. Gbọ́n, ọmọ mi, kí o sì mú ayọ̀ wá sínú ọkàn minígbà náà ni mo le dá gbogbo ẹni tí ó bá kẹ́gàn mi.

12. Ọlọ́gbọ́n rí ewu, ó sì fara pamọ́ṣùgbọ́n aláìgbọ́n rí kàkàkí ó dúró ó tẹ̀ṣíwájú, ó sì jìyà rẹ̀.

13. Gba aṣọ ẹni tí ó ṣe onídùúró fún àjòjìfi ṣe ẹ̀rí ìdúró bí o bá ṣe onídùúró fún obìnrin oní ìṣekúṣe.

14. Bí ènìyàn kan ń kígbe e ṣúre fún aládùúgbò rẹ ní òwúrọ̀a ó kà á sí bí èpè.

15. Àyà tí ó máa ń jà dàbíọ̀wààrà òjò ní ọjọ́ tí òjò ń rọ̀;

16. dídá a lẹ́kun dàbí ìgbà tí ènìyàn ń dá afẹ́fẹ́ lẹ́kuntàbí bí ẹni tí ó gbá òróró.

17. Bí irin tí ń pọ́n irin múbẹ́ẹ̀ ni ènìyàn kan ń pọ́n ẹlòmíràn mú.

18. Ẹni tí ó tọ́jú igi ọ̀pọ̀tọ́ yóò jẹ èṣo rẹ̀ẹni tí ó sì fojú tó ọ̀gá rẹ̀ yóò gba ọlá.

Ka pipe ipin Òwe 27