Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 25:18-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Bí àdá, idà tàbí ọ̀kọ̀ tí ó múni ènìyàn tí ó jẹ́rìí èké lòdì sí aládùúgbò rẹ̀.

19. Bí eyín tí ó bàjẹ́ tàbí ẹṣẹ̀ tí ó rọni ìgbẹ́kẹ̀lé lórí aláìṣòótọ́ ní àsìkò ìdàámú.

20. Bí ẹni tí ó bọ́ra kalẹ̀ ní ọjọ́ tí òtútù mú,tàbí iyọ̀ tí a fi ra ojú egbò ọgbẹ́ tàbí bí ọtí kíkan tí a dà sórí sódàní ẹni tí ń kọ orin sí ọkàn tí ó bàjẹ́.

21. Bí ebi bá ń pa ọ̀tá rẹ, fún un ní oúnjẹ jẹ;bí òrùngbẹ bá ń gbẹ ẹ́, fún un ní omi mú.

22. Nípa ṣíṣe báyìí, ìwọ yóò wa ẹ̀yín iná lé e lórí Olúwa yóò sì san ọẹ̀san rẹ̀ fún ọ.

23. Bí afẹ́fẹ́ gúṣù ti í mú òjò wá,bí ahọ́n tí ń sọ̀rọ̀ ẹ̀yìn ṣe ń mú ojú ìbínú wá.

24. Ó sàn láti gbé ní ibi igun kan lórí òrùléju láti bá aya oníjà gbé ilé pọ̀.

25. Bí omi tútù sí ẹni tí òrùngbẹ ń gbẹni ìròyìn ayọ̀ láti ọ̀nà jíjìn.

26. Bí ìsun tí ó di àbàtà tàbí kanga tí omi rẹ̀ bàjẹ́ni olódodo tí ó fi àyè gba ènìyàn búburú.

27. Kò dára láti jẹ oyin àjẹjù,bẹ́ẹ̀ ni kò pọ́nni lé láti máa wá ọlá fún ara ẹni.

Ka pipe ipin Òwe 25