Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 25:11-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Ọ̀rọ̀ tí a sọ ní àkókò tí ó yẹó dàbí èṣo wúrà nínú àpẹẹrẹ fàdákà.

12. Bí i yẹtí wúrà tàbí ohun ọ̀ṣọ́ ti wúrà dáradárani ìbáwí ọlọ́gbọ́n fún etí tí ó bá fetísílẹ̀.

13. Bí títutù òjò yìnyín ní àsíkò ìkórèni ìránṣẹ́ tí ó jẹ́ olóòtọ́ sí àwọn tí ó rán anó ń tu ọ̀gá rẹ̀ nínú.

14. Bí ojú ṣíṣú àti afẹ́fẹ́ láì sí òjòni ènìyàn tí ń yangàn nípa ẹ̀bùn tí kò fún ni.

15. Nípa ṣùúrù a lè yí ọba lọ́kàn padàahọ́n tí ń sọ̀rọ̀ rírọ̀ sí egungun.

16. Bí ìwọ bá rí oyin, jẹ ẹ́ ní ìwọ̀nbabí o bá jẹ ẹ́ jù, ìwọ yóò sì bì í.

17. Má ṣe máa lọ sí ilé aládùúgbò rẹ nígbà gbogbotàbí kí ó máa lọ ṣíbẹ̀ lálọ jù, yóò sì kórìíra rẹ.

18. Bí àdá, idà tàbí ọ̀kọ̀ tí ó múni ènìyàn tí ó jẹ́rìí èké lòdì sí aládùúgbò rẹ̀.

19. Bí eyín tí ó bàjẹ́ tàbí ẹṣẹ̀ tí ó rọni ìgbẹ́kẹ̀lé lórí aláìṣòótọ́ ní àsìkò ìdàámú.

20. Bí ẹni tí ó bọ́ra kalẹ̀ ní ọjọ́ tí òtútù mú,tàbí iyọ̀ tí a fi ra ojú egbò ọgbẹ́ tàbí bí ọtí kíkan tí a dà sórí sódàní ẹni tí ń kọ orin sí ọkàn tí ó bàjẹ́.

21. Bí ebi bá ń pa ọ̀tá rẹ, fún un ní oúnjẹ jẹ;bí òrùngbẹ bá ń gbẹ ẹ́, fún un ní omi mú.

22. Nípa ṣíṣe báyìí, ìwọ yóò wa ẹ̀yín iná lé e lórí Olúwa yóò sì san ọẹ̀san rẹ̀ fún ọ.

23. Bí afẹ́fẹ́ gúṣù ti í mú òjò wá,bí ahọ́n tí ń sọ̀rọ̀ ẹ̀yìn ṣe ń mú ojú ìbínú wá.

Ka pipe ipin Òwe 25