8. Ọ̀nà ẹlẹ́ṣẹ̀ kún fún ìwà ẹ̀ṣẹ̀ṣùgbọ́n iṣẹ́ onínú funfun jẹ́ títọ́.
9. Ó sàn láti máa gbé ní kọ̀rọ̀ orí òrùléju láti ṣe àjọpín ilé pẹ̀lú aya oníjà.
10. Ènìyàn búburú ń fẹ́ ibialádùúgbò rẹ̀ kì í rí àánú kankan gbà lọ́dọ̀ rẹ̀.
11. Nígbà tí a bá ń fìyà jẹ ẹlẹ́gàn, òpè a máa kọ́gbọ́n.
12. Olódodo ṣàkíyèsí ilé ènìyàn búburúó sì mú ènìyàn búburú wá sí ìparun.
13. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ti di etí rẹ̀ sí igbe olùpọ́njú,òun tìkárarẹ̀ yóò ké pẹ̀lú;ṣùgbọ́n a kì yóò gbọ́.
14. Ọ̀rẹ́ ìkọ̀kọ̀, mú ìbínú kúrò:àti owó-àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti ibi ìkọ̀kọ̀ wá,dẹ́kun ìbínú líle.
15. Ayọ̀ ni fún olódodo láti ṣe ìdájọ́:ṣùgbọ́n ìparun ni fún àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.
16. Ẹni tí ó bá yà kúrò ní ọ̀nà òye,yóò máa gbé inú ìjọ àwọn òkú.
17. Ẹni tí ó bá fẹ́ afẹ́, yóò di talákà:ẹni tí ó fẹ́ ọtí-wáìnì pẹ̀lú òróró kò le lọ́rọ̀.
18. Ènìyàn búburú ni yóò ṣe owó-ìràpadà fún olódodo,àti olùrékọjá fún ẹni dídúró-ṣinṣin.
19. Ó sàn láti jókòó ní ihà ju pẹ̀lúoníjà obìnrin àti òṣónú lọ.
20. Ìṣúra iyebíye àti òróró wà ní ibùgbé ọlọ́gbọ́n;ṣùgbọ́n ènìyàn aṣiwèrè (òmùgọ̀) jẹ ẹ́ run.
21. Ẹni tí ó bá tẹ̀lé òdodo àti àánú yóò rí ìyè,òdodo, àti ọlá.