Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 21:18-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Ènìyàn búburú ni yóò ṣe owó-ìràpadà fún olódodo,àti olùrékọjá fún ẹni dídúró-ṣinṣin.

19. Ó sàn láti jókòó ní ihà ju pẹ̀lúoníjà obìnrin àti òṣónú lọ.

20. Ìṣúra iyebíye àti òróró wà ní ibùgbé ọlọ́gbọ́n;ṣùgbọ́n ènìyàn aṣiwèrè (òmùgọ̀) jẹ ẹ́ run.

21. Ẹni tí ó bá tẹ̀lé òdodo àti àánú yóò rí ìyè,òdodo, àti ọlá.

22. Ọlọ́gbọ́n gòkè odi ìlú àwọn alágbára,ó sì bi ibi-gíga agbára ìgbẹ́kẹ̀lé wọn ṣubú.

23. Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ẹnu àti ahọ́n rẹ̀ mọ́,ó pa ọkàn rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ìyọnu.

24. Agbéraga àti alágídí ènìyàan ń gan orúkọ ara rẹ̀ nítorí ó ń hùwà nínú ìwà ìgbéraga rẹ̀,tí ń hùwà nínú àdábọwọ́ ìgbéraga.

25. Ẹlẹ́rìí èké yóò ṣègbé, àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ yóò parun láé;nítorí tí ọwọ́ rẹ̀ kọ iṣẹ́ ṣíṣe.

26. Ó ń fi ìlara ṣojúkòkòrò ní gbogbo ọjọ́:ṣùgbọ́n olódodo a máa fi fún ni kì í sì í dáwọ́ dúró.

27. Ẹbọ ènìyàn búburú, ìríra ni:mélòómélòó ni nígbà tí ó mú un wá pẹ̀lú èrò ìwà-ibi?

28. Ẹlẹ́rìí èké yóò ṣègbé:ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ẹni tí ó gbọ́, yóò dúró.

29. Ènìyàn búburú mú ojú ara rẹ̀ le:ṣùgbọ́n ẹni ìdúró-ṣinṣin ni ó ń mú ọ̀nà rẹ̀ tọ́.

30. Kò sí ọgbọ́n, kò sí ìmòye,tàbí ìmọ̀ràn tí ó le mókè níwájú Olúwa.

31. A ń múra ẹṣin sílẹ̀ de ọjọ́ ogun:ṣùgbọ́n ìṣẹ́gun jẹ́ ti Olúwa.

Ka pipe ipin Òwe 21