Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 19:26-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

26. Ẹni tí ó já baba rẹ̀ lulẹ̀, tí ó sì lé ìyá rẹ̀ jádeó jẹ́ adójútini ọmọ.

27. Yéé tẹ́tí sí ẹ̀kọ́ tí í mú ni ṣìnà ọmọ mi,ìwọ kì yóò sì sìnà kúrò nínú ọ̀rọ̀ ìmọ̀.

28. Ajẹ́rìí tí ó bàjẹ́ máa ń kẹ́gàn ìdájọ́ òtítọ́ẹnu ènìyàn búburú sì ń gbé ibi mi.

29. A ti pèṣè ìjìyà sílẹ̀ fún ẹlẹ́gàn;àti pàṣán fún ẹ̀yìn aláìgbọ́n.

Ka pipe ipin Òwe 19