Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 19:19-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Ènìyàn onínú-fùfù gbọdọ̀ gba èrè ìwà rẹ̀bí ìwọ bá gbàá là, ìwọ yóò tún ní láti ṣe é lẹ́ẹ̀kan síi.

20. Fetí sí ìmọ̀ràn kí o sì gba ẹ̀kọ́ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín ìwọ yóò di ọlọ́gbọ́n.

21. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ète inú ọkàn ènìyànṣùgbọ́n ìfẹ́ Olúwa ní ó máa ń borí.

22. Ohun tí ènìyàn ń fẹ́ ni ìfẹ́ tí kì í yẹ̀;ó sàn láti jẹ́ talákà ju òpùrọ́ lọ.

23. Ìbẹ̀rù Olúwa ń mú ìyè wá:nígbà náà ọkàn ń balẹ̀, láì sí ewu.

24. Ọ̀lẹ ki ọwọ́ rẹ̀ bọ inú àwo oúnjẹ;kò tilẹ̀ ní mú u padà wá sí ẹnu rẹ̀.

25. Na ẹlẹ́gàn, òpè yóò sì kọ́gbọ́n;bá olóye ènìyàn wí, yóò sì ní ìmọ̀ síi.

26. Ẹni tí ó já baba rẹ̀ lulẹ̀, tí ó sì lé ìyá rẹ̀ jádeó jẹ́ adójútini ọmọ.

27. Yéé tẹ́tí sí ẹ̀kọ́ tí í mú ni ṣìnà ọmọ mi,ìwọ kì yóò sì sìnà kúrò nínú ọ̀rọ̀ ìmọ̀.

28. Ajẹ́rìí tí ó bàjẹ́ máa ń kẹ́gàn ìdájọ́ òtítọ́ẹnu ènìyàn búburú sì ń gbé ibi mi.

29. A ti pèṣè ìjìyà sílẹ̀ fún ẹlẹ́gàn;àti pàṣán fún ẹ̀yìn aláìgbọ́n.

Ka pipe ipin Òwe 19