Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 18:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ènìyàn tí kò báni rẹ́ a máa lépa ìmọ̀ ara rẹ̀;ó kọjú ìjà sí gbogbo ìdájọ́ òdodo.

2. Aláìgbọ́n kò rí inú dídùn sí òyeṣùgbọn ó ní inú dídùn sí ṣíṣọ èrò tirẹ̀.

3. Nígbà ti ènìyàn búburú dé ni ẹ̀gàn dénígbà ti ẹ̀gàn dé ni ìtìjú dé.

4. Ọ̀rọ̀ ẹnu ènìyàn jẹ́ omi jínjìnṣùgbọ́n oríṣun ọgbọ́n jẹ́ odò tí ń ṣàn.

5. Kò dára kí ènìyàn ṣe ojúṣáájú fún ènìyàn búburútàbí kí a fi ìdájọ́ òdodo du aláìṣẹ̀.

Ka pipe ipin Òwe 18