Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 17:9-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Ẹni tí ó fojú fo ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ẹ́ mú kí ìfẹ́ gbòòrò sí i.Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ń tẹnumọ́ ọ̀rọ̀ yóò pín ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ méjì níyà.

10. Ọ̀rọ̀ ìbáwí dun ènìyàn olóyeju ọgọ́rùn ún pàsán lẹ́yìn aláìgbọ́n.

11. Oríkunkun ni ènìyàn ìkà máa ń ṣe,ìjòyè aláìláàánú ni a ó rán sí i.

12. Ó sàn kí ènìyàn pàdé béárì tí a ti kó lọ́mọjù aláìgbọ́n nínú ìwà òmùgọ̀ rẹ̀.

13. Bí ènìyàn kan bá fi ibi san ire,ibi kì yóò kúrò nílé rẹ̀ láéláé.

14. Bíbẹ̀rẹ̀ ìjà dàbí ẹni tí ó dá ojú fún adágún ominítorí náà mẹ́nu kúrò nínú ọ̀rọ̀ kí ó tó di ìjà.

15. Gbígbé ẹ̀bi fún aláre àti dídá ẹni jàre lẹ́bi, Olúwa kóríra méjèèjì.

16. Kí ni ìwúlò owó lọ́wọ́ aṣiwèrèníwọ̀n bí kò ti ní èròńgbà láti rí ọgbọ́n?

17. Ọ̀rẹ́ a máa fẹ́ni nígbà gbogbo,Arákùnrin sì wà fún ìgbà ìpọ́njú.

18. Ènìyàn aláìgbọ́n ṣe ìbúraó sì ṣe onídùúró fún aládùúgbò rẹ̀.

19. Ẹni tí ó fẹ́ràn ìjà fẹ́ràn ẹ̀ṣẹ̀;ẹni tí ó kọ́ ibodè gígàn ń wá ìparun.

20. Ènìyàn aláyìídáyidà ọkàn kì í gbèrúẹni tí ó ní ahọ́n ẹ̀tàn bọ́ sínú ìyọnu.

21. Láti bí aláìgbọ́n lọmọ a máa fa ìbànújẹ́ ọkànkò sí ayọ̀ fún baba ọmọ tí kò gbọ́n.

22. Ọkàn tí ó túká jẹ́ ogún gidiṣùgbọ́n ọkàn tí ó bàjẹ́ a máa mú kí egungun gbẹ.

Ka pipe ipin Òwe 17