Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 17:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Òkèlè gbígbẹ tòun tàlàáfíà àti ìdákẹ́jẹ́ sànju ilé tí ó kún fọ́fọ́ fún ẹran àti ìjà.

2. Ọlọ́gbọ́n ìránṣẹ́ yóò ṣàkóso adójútini ọmọ,yóò sì pín ogún gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ.

3. Iná ni a fi fọ́ Sílífà àti wúràṢùgbọ́n Olúwa ló ń dán ọkàn wò.

4. Ènìyàn búburú ń tẹ́tí sí ètè tí ń sọ ibiòpùrọ́ a máa fetí sí ahọ́n búburú.

5. Ẹni tí ó fi talákà ṣe yẹ̀yẹ́ kórìíra ẹlẹ́dàá talákà náàẹnikẹ́ni tí ń yọ̀ torí ìyọnu kò ní lọ láìjìyà.

6. Ọmọ-Ọmọ ni adé orí arúgbóòbí sì ni ìyangàn àwọn ọmọ.

7. Ọ̀rọ̀ dídùn kò yẹ aláìgbọ́n, mélòómélòó ni ètè tí ń parọ́ fún àwọn alákóso!

8. Àbẹ̀tẹ́lẹ̀ jẹ́ oògùn fún ẹni tí ó ń fún ni ohungbogbo, ibikíbi tí ó bá tẹ̀ sí ni ó ń yege.

9. Ẹni tí ó fojú fo ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ẹ́ mú kí ìfẹ́ gbòòrò sí i.Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ń tẹnumọ́ ọ̀rọ̀ yóò pín ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ méjì níyà.

10. Ọ̀rọ̀ ìbáwí dun ènìyàn olóyeju ọgọ́rùn ún pàsán lẹ́yìn aláìgbọ́n.

11. Oríkunkun ni ènìyàn ìkà máa ń ṣe,ìjòyè aláìláàánú ni a ó rán sí i.

12. Ó sàn kí ènìyàn pàdé béárì tí a ti kó lọ́mọjù aláìgbọ́n nínú ìwà òmùgọ̀ rẹ̀.

Ka pipe ipin Òwe 17