Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 16:4-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Olúwa ti ṣe ohun gbogbo láti mú kí ó rí bí ó ṣe fẹ́Kódà ènìyàn búburú fún ọjọ́ ìpọ́njú.

5. Olúwa kórìíra gbogbo ẹni tí ń gbéraga lọ́kàn rẹ̀mọ èyí dájú pé wọn kò ní lọ láìjìyà.

6. Nípaṣẹ̀ ìfẹ́ àti òtítọ́ a ṣètùtù ẹ̀ṣẹ̀nípaṣẹ̀ ìbẹ̀rù Olúwa ènìyàn sá fún ibi.

7. Nígbà tí ọ̀nà ènìyàn bá tẹ́ Olúwa lọ́rùn,yóò mú kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ gàn-án bá a gbé ní àlàáfíà.

8. Ó sàn kí ó kéré pẹ̀lú òdodoju èrè púpọ̀ pẹ̀lú èrú.

9. Ènìyàn a máa pète ọ̀nà ara rẹ̀ lọ́kàn an rẹ̀ṣùgbọ́n Olúwa ní í pinnu ìgbésẹ̀ rẹ̀.

10. Ètè ọba a máa sọ̀rọ̀ nípa inú síiẹnu rẹ̀ kò gbọdọ̀ gbé ẹ̀bi fún ara rẹ̀.

11. Òdiwọ̀n àti òṣùwọ̀n òtítọ́ wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa;gbogbo wíwúwo àpò jẹ́ láti ọwọ́ rẹ̀.

12. Àwọn ọba kórìírà ìwà àìtọ́nítorí òdodo ní í fi ìdí ìtẹ́ múlẹ̀.

13. Àwọn ọba ní inú dídùn sí ètè tí ń ṣòótọ́ènìyàn tí ń sọ òtítọ́ ṣe iyebíye sí wọn.

14. Ìrànṣẹ́ ikú ni ìbínú ọba jẹ́ṣùgbọ́n ọlọgbọ́n ènìyàn yóò tù ú nínú.

15. Nígbà tí ojú ọba bá túká, ó túmọ̀ sí ìyè;ojú rere rẹ̀ dàbí i ṣíṣú òjò ní ìgbà òjò.

Ka pipe ipin Òwe 16