Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 16:23-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. Ọkàn ọlọgbọ́n ènìyàn a máa ṣọ́ ẹnu rẹ̀ètè rẹ̀ sì ń mú kí ẹ̀kọ́ gbèrú.

24. Ọ̀rọ̀ ìtura dàbí afárá oyinó dùn fún ọkàn, ó sì fi ìlera fún egungun.

25. Ọ̀nà kan tí ó dàbí i pé ó dára lójú ènìyànṣùgbọ́n ní ìgbẹ̀yìn a ṣokùnfà ikú.

26. Ìfẹ́-àti-jẹun alágbàṣe ń ṣiṣẹ́ fún unnítorí ebi rẹ̀ mú kí ó máa ṣiṣẹ́ ni.

27. Ènìyàn búburú ń pèteọ̀rọ̀ rẹ̀ sì dàbí i iná tí ń jóni.

28. Aláyìídáyidà ènìyàn dá ìjà sílẹ̀olófòófó a sì máa pín ọ̀rẹ́ kòríkòsùn níyà.

29. Oníjàgídíjàgan ènìyàn tan aládùúgbò rẹ̀ó sì mú un sọ̀kalẹ̀ lọ sí ọ̀nà tí kò dára.

30. Ẹni tí ń ṣẹ́jú ń pètekéte;ẹni tí ó ṣu ẹnu jọ ń pète aburú.

31. Ewú orí jẹ́ ògoìgbé ayé òdodo ní í múni débẹ̀.

32. Ó sàn láti jẹ́ oníṣùúrù ju ajagun ènìyàn lọ,ẹni tí ó pa ìbínú mọ́ra ju ajagun-gbàlú lọ.

Ka pipe ipin Òwe 16