21. Àwọn tí ó gbọ́n nínú ọkàn là ń pè ní olóyeọ̀rọ̀ ìtura sì ń mú ẹ̀kọ́ gbèrú.
22. Òye jẹ́ oríṣun ìyè fún àwọn tí ó ní i,ṣùgbọ́n ìwà òmùgọ̀ ń kó ìyà jẹ aláìgbọ́n.
23. Ọkàn ọlọgbọ́n ènìyàn a máa ṣọ́ ẹnu rẹ̀ètè rẹ̀ sì ń mú kí ẹ̀kọ́ gbèrú.
24. Ọ̀rọ̀ ìtura dàbí afárá oyinó dùn fún ọkàn, ó sì fi ìlera fún egungun.
25. Ọ̀nà kan tí ó dàbí i pé ó dára lójú ènìyànṣùgbọ́n ní ìgbẹ̀yìn a ṣokùnfà ikú.
26. Ìfẹ́-àti-jẹun alágbàṣe ń ṣiṣẹ́ fún unnítorí ebi rẹ̀ mú kí ó máa ṣiṣẹ́ ni.
27. Ènìyàn búburú ń pèteọ̀rọ̀ rẹ̀ sì dàbí i iná tí ń jóni.
28. Aláyìídáyidà ènìyàn dá ìjà sílẹ̀olófòófó a sì máa pín ọ̀rẹ́ kòríkòsùn níyà.
29. Oníjàgídíjàgan ènìyàn tan aládùúgbò rẹ̀ó sì mú un sọ̀kalẹ̀ lọ sí ọ̀nà tí kò dára.
30. Ẹni tí ń ṣẹ́jú ń pètekéte;ẹni tí ó ṣu ẹnu jọ ń pète aburú.
31. Ewú orí jẹ́ ògoìgbé ayé òdodo ní í múni débẹ̀.
32. Ó sàn láti jẹ́ oníṣùúrù ju ajagun ènìyàn lọ,ẹni tí ó pa ìbínú mọ́ra ju ajagun-gbàlú lọ.